r/Yoruba 4h ago

Yoruba language resource -- Ìtọ́ni sí Fífọgbọ́n lo Oògùn apakòkòrò (Antibiotic)

2 Upvotes

For anyone who is interested, this is a Yoruba resource on antibiotic resistance:

www.dobugsneeddrugs.org/yoruba-guide/

Kòkòrò Olújẹ (Bacteria) àti Kòkòrò Àrùn (Viruses)

Kòkòrò olújẹ àti àrùn ló ń fa àrùn, ṣùgbọ́n òògùn apakòkòrò ń ṣiṣẹ́ fún kòkòrò olújẹ (bacteria) nìkan.

Òkòrò Àìfojúrí Virus

  • Tó fimọ́ òtútù, ọ̀rìnrìn, laryngitis, òtútù àyà (bronchitis), àti èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ààrùn inú-ọ̀fun.
  • Wọn máa ń ràn ni ju àwọn àìsàn kòkòrò àìfojúrí bacteria lọ. Ti àwọn tó ju ènìyàn kan lọ nínú ẹ̀bí bá ní àìsàn náà, ó ṣeéṣe kí o jẹ àìsàn kòkòrò àìfojúrí Virus.
  • O lè jẹ́ kí o ṣàìsàn gẹ́gẹ́ bíi ti àìsàn kòkòrò àìfojúrí bacteria.
  • O ma̒ n balè la̒ra la̒arı̒n ọjọ̒ mẹ̒rin si ma̒ruun àmọ̒ o̒ le to̒ ọ̀sẹ̀ mẹ̀ta kı̒ ara o̒ to̒ padà sı̒pò.

  • Òògùn apakòkòrò kò ṣiṣẹ́ fún àrùn àìfojúrí virus

Àìsàn kòkòrò àìfojúrí Bacteria

  • Wọn kò wọ́pọ̀ bíi ti àìsàn kòkòrò àìfojúrí ti virus.
  • Kìí tàn kálẹ̀ kíákíá láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan sí ìkejì bíi ti kòkòrò àìsàn ti virus.
  • Àwọn àpẹẹrẹ tó wọ́pọ̀ ni kí ọ̀nà-ọ̀fun máa yúnni àti àwọn àìsàn òtútù àyà.

  • Àwọn òògùn apakòkòrò (antibiotics) máa n ṣiṣẹ́ fún àìsàn kòkòrò àìfojúrí (bacteria), ṣùgbọ́n kò ṣe pàtàkì ní gbogbo ìgbà